| ENG Nigeria SPA Nigeria |
àwọn orírun
Ní ti ìpilẹ̀ṣẹ̀, orúkọ náà tí í ṣe ‘Nàìjíríà’ ni a ṣẹ̀dá ní ọdún 1897 láti inú ọ̀rọ̀ méjì tí í ṣe ‘Niger’ àti “agbègbè”, tí Niger sì ń sọ̀rọ̀ nípa odò kan tí ó gbajúmọ̀ tí ó ń ṣàn ní orílẹ̀-èdè náà. Lẹ́yìn tí Nàìjíríà ti wà lábẹ́ ìmúnisìn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tẹ́lẹ̀, ó di orílẹ̀-èdè òmìnira ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹwàá ọdún 1960, láti ìgbà náà ni wọ́n sì ti ń pè é ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira àpapọ̀ ti Nàìjíríà (ìtàn Nàìjíríà). Lónìí, àwọn ènìyàn ti ó ń gbé inú orílẹ̀-èdè náà jẹ́ bí i okòó-lé-nígba mílíọ̀nù, ó lé méje (227 million).
àwọn orúkọ míràn
Nàìjíríà tún ń jẹ́‘Nàìjá’ (tàbí ‘9ja’) àti ‘WÀZOBÌÀ’ nínú àṣà gbajúmọ̀. ‘Nàìjá’ jẹ́ ọ̀rọ̀ kan nínú ẹ̀yà èdè Gẹ̀ẹ́sì tí à ń pè ní Píjìn Nàìjíríà, tí ó ń tọ́ka sí àwòrán rere ti ‘Nàìjíríà tuntun’, tí àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà fẹ́ fi hàn. ‘WÀZOBÌÀ’ jẹ́ àpapọ̀ ọ̀rọ̀ mẹ́ta tí ó túmọ̀ sí ‘wá’ ní èdè mẹ́ta ti orílẹ̀-èdè yìí, èyíinì ni WÁ (Yoruba), ZO (Hausa), and BIA (Ibo). A lè wò ‘WÀZOBÌÀ’ gẹ́gẹ́ bí i ọ̀nà kan láti ṣagbátẹrù ìṣọ̀kan láàárín onírúurú ní orílẹ̀-èdè tó ní àwọn èniyàn tó pọ̀ jù lọ ní Áfíríkà.
àkópọ̀
Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó wá láti onírúurú ẹ̀yà àti ìjọba, èdè ìbílẹ̀ wọn sì yàtọ̀ síra gan-an. Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ tí wọ́n ní “ẹ̀bùn èdè” sa ipá wọn gẹ́gẹ́bí alárinà èdè nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ láàárín àwọn ẹ̀yà àti ààlà orílẹ̀-èdè saájú àsìkò ìjọba amúnisìn. Iṣẹ́ alárinà èdè tún pọn dandan fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ aláṣeyọrí ní àkókò ìjọba amúnisìn. Èkíní, iṣẹ́ ògbufọ̀ èdè ni wọ́n fi ṣe ààyò, lẹ́yìn náà ni iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè, èyí sì jẹ́ àṣà tí wọ́n ń bá lọ títí di àkókò tí Nàìjíríà di ómìnira. Lónìí, ipò pàtàkì tí Nàìjíríà wà, gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè tí ó ní àwọn ènìyàn púpọ̀ jùlọ ní Áfíríkà tí ó sì ní ọ̀kan lára àwọn ètò ọrọ̀-ajé tí ó tóbi jùlọ, mú kí orílẹ̀-èdè náà wà ní ojútáyé nì àgbáyé. Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó múná dóko pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn nílò lílo àwọn iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè àti iṣẹ́ ògbufọ̀. Nítorí náà, àwọn iṣẹ́ èdè yìí ṣe pàtàkì gan-an.
Àwọn ìwádìí tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí tún ti fi hàn pé ọjà ń béèrè fún àwọn iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè àti iṣẹ́ ògbufọ̀, èyí sì ti fún ni ní àlàyé nípa àwọn ohun tí wọ́n nílò nínú àwọn ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àti nínú àwọn ẹ̀ka ẹ̀kọ́ méjèèjì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a nílò àwọn ìwádìí síwájú sí i, àwọn àbájáde tó wà nísinsìnyí fi hàn pé àwọn àlàfo ìdàgbàsókè wà nínú àwọn eka wọ̀nyí.
Àwọn ọ̀rọ̀ nípa Ìfúnlase àti ìlànà idiwọ́n jẹ́ kókó pàtàkì, bẹ́è sì ni dídára àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe nísinsìnyí pẹ̀lú, áti wíwà lárọ̀ọ́wọ́tó ẹ̀kọ́ tí ó dára ní ilé ẹ̀kọ́ gíga. Nínú àkọsílẹ̀ yi, a topinpin ìtàn ìtumọ̀ èdè àti ògbufọ̀ ̀edè ni Nàìjíríà, èyí sì kan ọ̀rọ̀ ìtumọ̀ èdè ẹ̀sìn àti ti ìwé kíkọ, ìlànà ìdiwọ́n àti àṣà, pẹ̀lú ẹ̀kọ́ àti ìwádìí nípa àwọn atúmọ̀ àti ògbufọ̀ èdè.
àkọsílẹ̀
| Oludamilola I. Oyetoyan & Segun Afolabi | |
| 2024 | |
| Oyetoyan, Oludamilola I. & Segun Afolabi. 2024. "Nàìjíríà" @ ENTI (Encyclopaedia of Translation & Interpreting). AIETI. | |
| https://doi.org/10.5281/zenodo.10949329 | |
| https://www.aieti.eu/enti/nigeria_YOR |