Olúdámilọlá I. Oyètóyan (olùkọ̀wé àti atúmọ̀ èdè)
Oyè ẹ̀kọ́ ti ọ̀mọ̀wé (PhD) nínú Ìmọ̀ Èdè àti Ìwádìí Ìtumọ̀ Èdè láti Yunifásítì Leipzig (2015). Ìrírí ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ káríi àwọn ẹ̀kọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ó tí kò ì tí gba oyè ẹ̀kọ́ àti ẹ̀kọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ó tí ó ti gba oyè ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ nínú ẹ̀kọ́ nípa èdè àti àṣà Jémáǹi, ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ àkópọ̀ ọ̀rọ̀ àti ẹ̀kọ́ fún àwọn olùkọ́ni èdè àjèjì ní Nàìjíríà àti ní Yunifásítì Bergen. Àwọn ohun tó jẹ ẹ́ lógún nínú ìwádìí rẹ̀ ni kíkónilẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ itúmọ̀ èdè, ̀iṣẹ́ ìbáraeniṣepọ̀ láàárín àwọn ènìyàn tí o ní onírúurú àṣà, àti àwọn ẹ̀kọ́ fún kikonilẹ̀kọ́ èdè ilẹ̀ òkèèrè. Ní báyìí, ó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí atúmọ̀ èdè aládàáni ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú iṣẹ́ olùkọ́ tí ó ń ṣe ní ilé ẹ̀kọ́ àwọn àgbàlagbà àti ilé ẹ̀kọ́ girama ní Ìpínlẹ̀ Vestland àti ìjọba ibilè Bergen. Àwọn èdè tí ó ń lò ní ibi iṣẹ́ atúmọ̀ èdè aládàáni náà ni Yorùbá, Gẹ̀ẹ́sì, Píjìn, Jémáǹi, àti èdè orílẹ̀-èdè Nòwé (Nòwéjíànì).
Ṣégun Afọlábí
Oyè ẹ̀kọ́ ti ọ̀mọ̀wé (PhD) nínú Ìwádìí Ìtumọ̀ láti Yunifásítì Laval (2018), Quebec, lẹ́yìn tí o ti kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí kò tíì gboyè jáde ní ẹ̀kọ́ ìtumọ̀ èdè fún ohun tó lé ní ọdún mẹ́wàá ní Nàìjíríà. Àwọn ohun tí ó ń ṣe ìwádìí rẹ̀ ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àwọn atúmọ̀ èdè/ogbufò èdè, àyẹ̀wò àwọn àìní ọjà ìtumọ̀ èdè, àwọn akoso ìtumọ̀ èdè, ìtumọ̀ èdè fún iṣèlú, ẹ̀kọ́ nípa àwùjọ ìtumọ̀ èdè, ìtàn ìtumọ̀ èdè àti àwọn irinṣẹ́ ìtumọ̀ èdè lórí i ero ayarabiàṣà. Ó jẹ́ atúmọ̀ èdè tí tí a jẹ́rìí gbè tó sì ní ìẃé ẹ̀rí ìjọba, ó sì jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Ordre des traducteurs, terminologues et interprètes agréés du Québec (OTTIAQ) àti ti Àjọ Àwọn Atúmọ̀ àti Ògbufọ̀ èdè ti New Brunswick (CTINB). Ní báyìí, Ó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí atúmọ̀ èdè / ògbufọ̀ èdè aládàáni, bakan náà, ó sì tún ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ Àjọṣepọ̀ (fún gbigba àwọn akẹ́kọ̀ọ àgbáyé si ile ekó) ní Yunifásítì Moncton, eka ti Edmundston.̣̣̀̀
Adejọkẹ Yewande Oluwajọbi (Atúmọ̀ èdè)
Oyè ẹ̀kọ́ nínú ìmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Yorùbá ní ilé ẹkọ́ Olùkọ́ni Adeniran Ogunsanya, Ijanikin ní ilù Eko. O tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ifásitì Ọbafẹmi Awolọwọ Ilé-Ifẹ̀ níbi tí ó ti kàwé gboyè nínú ìmọ̀ ìbáraẹniṣepọ̀ lágbayé (B.Sc International Relations). Ó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ atúmọ̀ èdè pẹ̀lú ìrírí ọdún méjìlá, ó sì ní òye ìlò àwọn ohun èlò ibanisoro ìgbàlódé. Ó tún jẹ́ akàròyìn ní ẹka èdè Yoruba ní ilé iṣẹ́ móhùn-máwòrán ìjọba àpapọ̀ orìlẹ̀-èdè Nàìjíríà (NTA - Nigerian Television Authority) Ìkànnì Oòduà. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ògbufọ̀ àti olùkópa nínú àkopọ̀ àwọn ewì àtẹnudẹ́nu ní ilẹ̀ Afirika (African Poems) èyítí wọn kọ sí èdè Yoruba. O máa n se isẹ́ ìtumọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì sí Yorùba tàbí Yorùbá sí èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ní báyìí, óun ni Akọ̀wé gbogbogbòò àti Olùbójútó Ìforúkọsílẹ̀ fún Àjọ àwọn Ògbufọ̀ àti àwọn Atúmọ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà (Nigerian Institute of Translators and Interpreters – NITI).