Skip navigation

Àròkọ

home page help (reference guide) search download (pdf) print broken link

 

 

citation ENG Nigeria SPA Nigeria

 

àkóónú
Ọ̀rọ̀ Ìsaájú | Ìtàn ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè ní Nàìjíríà | Ìtumọ̀ èdè àti ògbufọ̀ èdè lẹ́yìn òmìnira àti ní Nàìjíríà òde òní | Ẹkọ́ ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè (TIS) | Ìwádìí Ojo Iwaju

    

Introduction  Ọ̀rọ̀ Ìsaájú

Ǹaìjíríà jẹ́ orílẹ́-èdè tí ó kún fún èdè púpọ̀, nítòótọ́, ó jẹ́ irúu Bábeĺì. Àwọn èdè ẹgbàálélọ́gọ́jọ ó dín méjì (2,158)  ni ó wà ní ̀àḳọsílẹ̀ gẹ́gẹ́bí èdè àbínibí ní orílẹ́-èdè mẹ́rìnléláàdọ́ta (54) ní ilẹ̀ Áfíríkà, tí ó sì jẹ́ wípé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ nípa ènìyàn àti àṣà pẹ̀lú iṣe wọn kọ àkọsílẹ̀ nípa àwọn èdè okòólélẹ́ẹ̀édẹ́gbẹ̀ta (520) tí a ṣì ń sọ lọ́wọ́lọ́wọ́, ti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́wàá (510) nínú wọn jẹ́ èdè àbínibí láti orílé-èdè Nàíjírìa. (Eberhard, Simons & Fennig 2022: 39, 233, Adegbija 2004: 255-256). Àwọn èdè orílẹ̀-̀edè Nàìjíríà ni a pín sí ẹbí i Afro-Asiatic, Niger-Congo, Nilo-Saharan, àti Creole/Pijin, (Eberhard, Simons & Fennig 2022: 41, Adegbija 2004: 46).

Èdè àbínibí Nàijírìa mẹ́ta ni a ti gbé sókè gẹ́gẹ́bí èdè orílẹ̀-èdè, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú wọn jẹ́ èdè àbínibí ọ̀gọ̀ọ̀rò́ tí ó ju ọgbọ̀n (30) mílíọ̀nù (bí i ẹẹ́rìnlá nínú ọgọ́rùún, 14%) ènìyàn tí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè lọ. Iṣẹ́ ògbufọ̀ èdè àti pàápàá ìtumọ̀ èdè lárìíń àwọn èdè wọ̀nyí sí ara wọn ni wón ti ń ṣe ní orílẹ́-èdè tí a mọ̀ sí Nàíjírìa lónìí, láti àwọn àsìkò tí ó saájú ìmúnisìn. Àwọn èdè wọ̀nyí jẹ́ Haúsá (Àríwá àti Agbègbè àárín Nàíjiríà), Yorùbá (Gúúsù-Ìwò́-Oòrùn Nàíjírìa), àti Íbò (Gúúsù -Ìlà-Oòrùn Nàíjírìa) (Bandia 2008: 1-2, Adegbija 2004: 17-19). Obianika (2018: 4) pèsè ìlà-sílẹ́ kúkurú, bẹè sì ni Eberhard, Simons & Fennig (2022: 520-532) ṣe ìgbékalẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàyé.

Map of Nigeria
Ìgbékalẹ̀ èdè ti orílé-èdè Nàìjíríà ní kúkurú (Obianika 2018: 4)

Àwọn èdè tí kì í ṣe àbínibí ni Nàìjíríà ni Lárúbáwá, Potugíìsì, Faransé, Jémáǹi, èdè orílẹ̀-èdè Rọ́síà, Ítálì, Ṣaina, Sípéènì, àti Gẹ̀ẹ́sì. Ní ònà kíní, nígbàtí àwón oníṣòwò láti Ìlú-Ọba àti àwọn oníhìnrere ti àwọn Onígbàgbọ́ dé ní òpin ọ̀ọ́rúndún 1500, ni a gbé èdè Gẹ̀ẹ́sì kalẹ̀ tí wọ́n sì fi ipá sọ ọ́ di èdè ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ní àsìkò ìmúnisìn. Lẹ́yìn náà ni wọ́n gbà á gẹ́gébí èdè àjọmọ̀ lẹ́yìn ìmúnisìn, lápá kan, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè tí ó wà ní orílẹ̀-̀edè náà (Richards & Schmidt 2002: 309, Allan 1978: 412, Simpson 1979: 75, Adegbija 2004: 16-19). Àwọn èdè àbínibí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí a ti sọ̀rọ̀ wọn sẹ́yìn ni a kà sí èdè orílẹ́-èdè, nítorí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ iye àwọn tí ó ń sọ wọ́n, tí a sì dá wọn mọ̀ fún èdè ìbánisọ̀rọ̀ ní orílẹ́-èdè, ní àfikún sí èdè Gẹ̀ẹ́sí (Adegbija 2004:49). Àwọn èdè orílé-èdè àti àwọn èdè míràn tí wọ́n ní ju mílíọ̀nù ènìyàn tí ó ń sọ wọ́n lọ ni oríṣiríṣi agbègbè ni a ń lò gẹ́gẹ́bi èdè ìbánisọ̀rọ̀ agbègbè pẹ̀lú àṣẹ ìjọba (Adegbija 2004: 48-49, 51).  

Ní ọ̀nà kejì, wọ́n lo àwọn èdè ìlú òkèèrè nínú ìbáṣepọ̀ tí ó wà láàárín àwọn ọmọ orílẹ́-èdè Nàìjíríà àti àwọn àjèjì saájú àsìkò ìmúnisìn, àwọn èdè wọ̀nyí sì ti di ara èdè tí a ń lò ní orílẹ́-èdè Nàìjíríà (Adegbija 2004: 46, Soyoye 2001: 31-35). Lákòótán, bí àwọn èdè àbínibí ní Nàìjíríà, àti àwọn èdè tí ó wá láti ibòmíràn ṣe ṣe pàtàkì tó ní láti ṣe pẹ̀lú ìlò wọn ní agbègbè kọ̀ọ̀kan àti ní ayẹyẹ tí ó yàtọ̀ sí ara wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èdè agbègbè ni a ń lò tí wọ́n jẹ́ àwọn èdè àjọmọ̀ agbègbè, kí a le sọ pé Nàìjíríà jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè àjọmọ̀ yato si Gẹ̀ẹ́si (Oyetoyan 2016: 213-214).

Pé ìbáraẹniṣepọ̀ jẹ́ kòṣeémánìí láàárín àwọn ẹ̀yà tí ó ní onírúurú èdè, tí a mọ̀ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, jẹ́ ohun tí ó ti wà kí a tó da àwọn ẹgbẹ́ èdè àti àṣà oríṣiríṣi papọ̀. Èyí ló mú kí ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ní èdè àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyí jẹ́ dandan, tí ó sì mú kí iṣẹ́ ògbufọ̀ èdè bẹ̀rẹ̀ sí ní dìde nínú ìbáraẹniṣepọ̀ àti ìbáraẹniṣòwòpọ̀ láàŕin ẹ̀yà sí ẹ̀yà. Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ onímọ̀-èdè, tí a le fi iṣẹ́ rẹ̀ wé iṣẹ atúmọ̀ àkọsilẹ̀ àti ògbufọ̀ èdè, ni ẹnití ó jẹ́ alárinà àwọn àbínibí méjì tí wọ́n ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ (Ukoyen 1979: 72, Bandia 2001: 295). Nínú ̀akọsílẹ̀ yìí, a gbé ìtàn ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè (T&I) ní Nàìjíríà ka 'lẹ̀, tí àtúnwò ìtumọ̀ èdè àwọn ẹ̀ka ìwé kíkọ àti ìtumọ̀ èdè àkọsílẹ̀ ti ẹ̀sìn sì tẹ̀lé e. Síwájú si, a gbé ọ̀rọ̀ ìdàgbàsókè ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè yẹ̀wò ní orílé-èdè Nàìjíríà lẹ́yìn àsìkò ìmúnisìn àti ní àsìkò ìgbàlódé. A parí àkọsílè yìí pẹ̀lú Ìwádìí Ọjọ́-Iwájú.

padà sí òkè

[heading title] Ìtàn ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè ní Nàìjíríà

Ìtàn iṣẹ́ ògbufọ̀ ní Nàìjíríà ni a lè tọ ipasẹ̀ rẹ̀ sí àsìkò tí ó ṣaájú ìmúnisìn nígbàtí àwọn aláṣẹ ìbílẹ̀ gb'ára lé àwọn tí ó ní ìmọ̀-èdè tí ó pọ̀ láti ṣe ògbufọ̀ ìkíni àti ìtàkùrọ̀sọ (Bandia 2001: 295). Àwọn ènìyàn ṣe ògbufọ̀ àwòrán àti ààmì fún ara wọn nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀. Irú iṣẹ́ ògbufọ̀ báyìí li a pín sí abẹ́ ẹ̀ka tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìtumọ̀ ààmì tàbí if̀arajúwe.

Ì̀béèrè fún iṣẹ ògbufọ̀ èdè láàárín èdè kan sí òmíràn lábẹ́ àṣẹ bẹ̀rẹ̀ lásìkò ìmúnisìn nígbàtí ìjọba nílò àwọn ògbufọ̀ tàbí àwọn ènìyàn díẹ̀ tí ó mọ ìwé kíkọ àti kíkà láti ṣe ògbufọ̀ láàárín ìjọba Gẹ̀ẹ́sì tí ó fi ipá tẹ̀dó àti àwọn aláṣẹ ̀ibílẹ̀, pẹ̀lú àwọn ará ìlú. Oyali (2018 : 92) pàápàá tọ ipasẹ̀ ìtàn iṣẹ́ ògbufọ̀ èdè ní àsìkò ìmúnisìn sí ìrìn àjò àkọ́kọ́ sí Niger, tí ó sì kọ ìròyìn pé àwọn Egbẹ́ Ìjọ Oníhìnrere (SÍẸ́MẸẸ̀SÌ, tí a tún mọ̀ sí Àwùjọ Oníhìnrere ti Krìstẹ́nì) pàṣẹ fún J. F. Schön, láti kọ́ àwọn ògbufọ̀ àti láti kọ́ àwọn èdè tí ó ṣe pàtàkì.

Gẹ́gẹ́bí a ṣe le retí, ìtumọ̀ èdè ní Nàìjíríà dàgbà sókè láti inú iṣẹ́ ògbufọ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu sísọ. ‘̀Awọn onímọ̀-èdè’ ṣe àkọjáde ìwé tí ó le ṣe ìtọ́sónà fún àwọn ìjọba amúnisìn (Ukoyèn 1979: 72, Bandia 2001: 298-299). Wọ́n tún ṣe iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè fún àwùjọ, àti pàápàá ìtumọ̀ èdè ti ẹ̀sin àti ti ìwé kíko (Bandia 2001: 298-299, Simpson 1979: 76-79).

Ìtumọ̀ ìwé tí a ti kọ: ìtàn àròsọ àti ìtàn àtẹnudẹ́nu

Àkópọ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ lẹ́nu ni àwọn ìtàn àròsọ, ìtàn àtẹnudẹ́nu, ewì, oŕikì (ti àwọn ènìyàn), ìtàn nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé nínú ìtàn, àwọn ohun èlò orin tó ń fara wé ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn nínú èdè Yorùbá tó ní ìró (Bandia 2008: 11, Ukoyen 1979: 72, Olaoyè & Otunuyi 2009: 122).

Ìlù Gángan jẹ́ gbajúmọ̀ lágbègbè Gúúsù Ìwọ̀ Oòrùn Nàìjíríà láàárín àwọn Yorùbá nígbà ayẹyẹ àti àjọyọ̀. Wọ́n máa ń lu Gángan láti jẹ́ kí áwọn ènìyàn mọ ohun tí wọ́n ń sọ àti láti yin àwọn ènìyàn. Nígbà míì, àwọn tó ń lu ìlù tàbí àwọn tó wà ní àwùjọ á wulẹ̀ máa sọ ohun tí ìlù náà ń sọ ní tààràtà, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti lu ìlù náà tán, ìyẹn sì jẹ́ ọ̀nà kan tí ó ní ṣe pẹ̀lú itumọ̀ ààmì tàbí ìf̀arajúwe (Bandia 2001: 296). Àwọn orísun àkópọ̀ ọ̀rọ̀ sísọ mìíràn ni a túmọ̀, àwon bí i “[...] àwọn ìwé orin ìsìn, àwọn orin, àwọn ọ̀rọ̀ orin, àwọn rárà, àwọn ìwàásù tí wọ́n ń kà láti inú Bíbélì àti Kùránì[...]” (Olaoyè & Otunuyi 2009: 122).

The forest of God
Ìwé àtayébáyé tí wọ́n kọ lí édè Yorùbá àti ìtumọ̀ rẹ̀ lí èdè Gẹ̀ẹ́sì

Nípa ti àwọn àkópọ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n dá lóríi àwọn àṣà àtenudenu, Bandia (2001: 299, 2008: 8) mú u wá sí ìrántí pé àwọn akọ̀wé ìbílẹ̀ ló túmọ̀ àwọn àkópọ̀ ọ̀rọ̀ sísọ sí èdè áwọn amúnisìn, ìyẹn èdè Gẹ̀ẹ́sì. Wọ́n gbé ètò láti kọ ìwé dìde (ìgbé dìde ètò ìkọ̀wé - wo Eberhard, Simons & Fennig 2022: 11). Àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wa máa ń ṣe àtúnṣe àwọn àkópọ̀ ọ̀rọ̀ èdè tí a ṣe ìtúmọ̀ sí láìṣe akitiyan láti fi wọ́n wé àwọn àkópọ̀ ọ̀rọ̀ èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀. Àwọn ìwé ìtàn àtẹnudẹ́nu kan nílẹ̀ Áfíríkà dá lórí àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, ìtàn àròsọ, àti àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu tí wọ́n fi orin kọ (Àlọ́ Àpagbè lí édè Yorùbá). Àwọn ìtàn àfẹnusọ ni wọ́n yí padà sí àkópọ̀ ọ̀rọ̀ kíkọ ní àwọn èdè ìbílẹ̀ ní àkókò ìmúnisìn, àti lẹ́yìn ìgbà náà sí èdè Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn kan lára àwọn ìwé wọ̀nyí ni wọ́n ti yí padà fún kíkọ́ èdè ìbílẹ̀ ní àwọn ilé ìwé àti fún ìwádìí ní ilé ẹ̀kọ́ gíga. Àwọn àpẹẹrẹ láti inú èdè Yorùbá ni àwọn iṣẹ́ ti D.O. Fagunwa Igbó Olódùmarè, tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ jáde lí ọ́dún 1949 (tí wọ́n túmọ̀ sí The forest of God - 1984), Ìrìnkèrindò nínú igbó Elégbèje - 1955 (a túmọ̀ rẹ̀ si Expeditions to the Mount of Thought - 1994), Ògbójú ọdẹ nínú igbó Irùnmọlè - 1950 (a túmọ̀ rẹ̀ si The forest of thousand daemons, a Hunter’s saga - 1968), àti Aláwìíyé ti Odunjo – 1943. Yàtọ̀ síyẹn, Olaoyè & Otuniyi (2009) ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìwé tó ṣe é túmọ̀ lẹ́yìn àsìkò ìjọba amúnisìn bí i “[...] àwọn àpẹẹrẹ ìtàgé, ewì, àṣàyàn ọ̀rọ̀, òwe, àkànlò èdè, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí kókó ọ̀rọ̀ èyíkéyìí, àwọn àkọsílẹ̀ òfin bíi ìwé òfin, àwọn ìwé ìròyìn, àwọn àkóso, àwọn ìwé ẹ̀rí, àwọn ìwé ìfilọ̀ [...] àti àwọn fíìmù [...]”.

Láfikún sí i, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé tí a kọ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ní àwọn àṣà ìbílẹ̀ Nàìjíríà ni a ti túmọ̀ wọn sí àwọn èdè ilẹ̀ Yúróòpù mìíràn. Palm Wine drinkard and the dead palmwine tapster (1952) ti Amos Tutuola bí àpẹẹrẹ, ni wọ́n túmọ̀ rẹ̀ sí èdè Jẹ́mánì gẹ́gẹ́bí i Der Palmweintrinker (Hilsbecher 1962). A ti túmọ̀ díẹ̀ lára àwọn ìwé Fagunwa tí a ti tọ́ka síwájú sí èdè Faransé ní òpin àsìkò tí ó tẹ̀lé òmìnira láti ọwọ́ ọ Olaoyè Abioyè. Bí àpẹẹrẹ, Ògbójú ọdẹ nínú igbó Irùnmọlè tí wọ́n túmọ̀ rẹ̀ sí Le preux chasseur dans la forêt infestée de démons (1989).

Ìtumọ̀ èdè ti ẹ̀sìn

Ẹ̀sìn ní ààyè tirẹ̀ nínú ìtàn ìtumọ̀ èdè ní Nàìjíríà. Ẹ̀sìn àbáláyé lí àwọn ènìyàn tí ń sìn nígbàtí ẹ̀sìn Ìslàámù àti tí àwọn Krìstìẹ́nì wọ Nàìjíríà nípasẹ̀ ìṣòwò àti iṣẹ́ ìhìnrere ní ọ̀rúndún kọkànlàá (11th) àti ọ̀rúndún kẹẹ́dógún (15th) lẹsẹse. (Falola & Heaton 2008 : xiii-xiv).

Pilgrim's Progress
Ìwé ẹ̀sìn àtayébáyé àti ìtumọ̀ rẹ̀ ní Yorùbá

Àwọn ọ̀nà àbáláyé ti sísin oríṣiríṣi òrìṣa farahàn nínú ìtàn àfẹnusọ, àlọ́ ìrìntàn, àti ìtàn ìṣẹ̀m̀báyé tí ó padà wá jẹ́ ohun tí a ń túmọ̀ ní àsìkò ìmúnisìn àti lẹ́yìn ìgbà náà. Śibẹ̀síbẹ̀, ̀itumọ̀ èdè Bíbélì Mímọ́, Kùránì Mímọ́ àti àwọn ìwé ẹ̀sìn tí ó jẹ mọ́ ẹ̀sìn Krìsténì tàbí Ìslàámù jẹ́ àpẹẹrẹ tí ó pọ̀ jù láàárín àwọn ìtumọ̀ èdè ti ẹ̀sìn. Ìtumọ̀ èdè ìwé ẹ̀sìn kan tí a le pè akíyèsi sí ni ti Bunyan (1856) sí èdè Yorùbá gẹ́gẹ́bí 'Ìlọsíwájú Èrò Mímó'̣ (1911), láti ọwọ́ Hinderer, tí a sọ nípa rẹ̀ nínú Adeaga (2008:  65).

Ìtumọ̀ èdè Bíbélì

A le tọ ipa ìtumọ̀ Bíbélì ní Nàìjíríà sí ọ̀rúndún kọkàndílógún (19) pẹ̀lú àwọn oníhìnrere láti ilẹ̀ àjòjì tí wọ́n ń kọ́   èdè àwọn àbínibí, tí wọ́n dá ìlànà láti kọ ìwé sílẹ̀, tí wọ́n sì ṣe gbogbo ìmúrasílẹ̀ tí ó yẹ fún ìtumọ̀ Bíbélì sí àwọn èdè Nàìjíríà (Amewowo 1986: 12). Ìtumọ̀ èdè Bíbélì Ẹ́fíìkì ni a kọ́kọ́ túmọ̀ lí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, pẹ̀lú Májẹ̀mu Láíláí, èyí tí a parí ní ọdún 1866, lẹ́yìn tí a ti parí Májẹ̀mu Titun ní ọdún 1862. Iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè náà jẹ́ nípa ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn oníhìnrere tí ó ń ṣisẹ́ pẹ̀lú Ẹgbẹ Ìjọ Oníhìnrere – SÍẸ́MẸẸ̀SÌ (CMS) ti Ìjó Skọ́tíláǹdì (Amewowo 1986: 13). Bẹ́è gẹ́gẹ́ ni a ṣe ìtumọ̀ èdè Bíbélì làti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Yorùbá ní ọdún 1884. Ọmọ orílẹ́-èdè Nàìjíríà tí ó ti jẹ́ ẹrú nígbà kan rí ní àsìkò ìmúnisìn, Sámúélì Àjàyí Crowther (1809-1891), tí a kọ́ ní ẹ̀kọ́, tí ó sì gba oyè Olórí Àlùfáà, ni ó ṣe ìtumọ̀ èdè Bíbélì nígbàtí ó ń gbé ilé alájà àkọ́kọ́ ní Àgbádárìgì, ní ìlú Èkó.

Bible Yoruba & Igbo
Àwọn ìtumọ̀ èdè Bíbélì Mimo ni Yoruba àti Ibo

Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míràn sí èdè Nàìjíríà láàárín àsìkò ìmúnisìn jẹ́ iṣẹ́ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn oníhìnrere Ilẹ̀ Òyìnbó àti Nàìjíríà. Àwọn SÍẸ́MẸẸ̀SÌ ni ó ṣe ìtumọ̀ Bíbélì Íbò ní ọdún 1906 (wo Amewowo 1986: 13, Oyali 2018: 87-88). A ṣe àtẹ̀jáde Bíbélì Haúsá lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ ní ọdún 1932, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àjọṣepọ̀ láàárín àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàì̀jíríà tí ó ní ìfẹ́ sí iṣẹ́ ìhìnrere ni àríwá Nàìjíríà pẹ̀lú àwọn Mùsùlùmí àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oníhìnrere (wọ́n tún ń pè wọ́n ní Ẹgbẹ́ Sùdánì, àti Ẹgbẹ́ Haúsá, Gaiya 1993: 55-56). Iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè Bíbélì ṣì ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́ ní Nàìjíríà òde-òní, a ó sì ma jíròrò nípa rẹ̀ síwájú sí i ní abala tí ó tẹ̀lé èyí.

Ìtumọ̀ èdè Kùránì

Láìdàbí ìtumọ̀ Bíbélì, ìtumọ̀ Kùránì sí èdè Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí́ Bandia gbé jáde (2005: 962):

Le Coran ne fut traduit en langues africaines que beaucoup plus tard, dans un effort pour conquérir le cœur et les esprits des populations locales. Le Coran fut ainsi traduit entre autres en hausa et en yoruba. On pense aussi que certains textes islamiques furent traduits en ajani (yoruba écrit en alphabet arabe) par les « malams » et que certaines de ces traductions ont été effectuées bien avant l’adoption de l’alphabet romain.

Quran
Àwọn ìtumọ̀ Kùránì sí Yorùbá àti Haúsá

Itúmọ̀ àkọ́kọ́ tí a mọ̀ nípa Kùránì sí èdè Áfíríkà ni Ìtumọ̀ si Yorùbá ti Ẹni ọ̀wọ̀ (Reverend) M.S. Cole, tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ jáde ní 1906, tí wọ́n tún tẹ̀ jáde ní 1924 (Solihu 2015). Oyewumi (2022) jiyàn wípé:

"the Ahmadiyya translation of the Holy Quran into Yoruba was part of a master plan chalked out by their leader (Mirza Bashirud-Din Mahmud, at QadiBn). Although the Ahmadiyya Mission in Nigeria had set up a committee in 1934 to consider such a translation, it was not until 1957 that the first portion of the Yoruba translation - the work of Alhaji H. O. Sanyaolu - was completed and published. The second edition, which included Suras al-Fatiha and al-Baqara, was published in Lagos in 1969, presenting 24 chapters in parallel columns with the original Arabic and the Yoruba translation."

Lónìí, àwọn ìtumọ̀ èdè Kùránì kan wà tí a túmọ̀ ní àwọn èdè Nàìjíríà míìràn bí i Ibo àti Hausa. Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé kò sí ìwé kíkọ púpọ̀ tó wà lórí i ̀ìtumọ̀ èdè Kùránì òde òní sí àwọn èdè Nàìjíríà.

padà sí òkè

[heading title] Ìtumọ̀ èdè àti ògbufọ̀ èdè lẹ́yìn òmìnira àti ní Nàìjíríà òde òní

Pẹ̀lú òmìnira tí Nàìjíríà gbà lí ọ́dún 1960, àwọn ojúṣe gẹ́gẹ́bí àjọ olóṣèlú olómìnira dé pẹ̀lú u kíkópa nínú àwọn ọ̀ràn àgbáyé. Ó sì wá jẹ́ dandan pé kí ìdàgbàsókè wà ní ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀ka, ki àjọṣepọ̀ sì wà pẹ̀lú àgbáyé pẹ̀lú. Àwọn àkóso èdè tuntun nígbà náà ń tẹ̀síwájú láti máa ṣàtìlẹyìn fún lílo èdè Gẹ̀ẹ́sì gẹ́gẹ́ bí èdè àjùmọ̀lò lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn èdè àjùmọ̀lò agbègbè mìíràn (wo ọ̀rọ̀ ìsaájú). Pẹ̀lú èdè Faransé gẹ́gẹ́bí i èdè ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nítòsí Nàìjíríà (fún àpẹẹrẹ, Bèníǹ, Kamẹrúùǹ, Nìjéè àti Sáàdì), gbígba àwọn òṣìṣẹ́ tó ni imọ èdè Faransé sí iṣẹ́ alárinà èdè di ohun tó pọn dandan fún àwọn àjọṣepọ orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè (Bandia 2001: 298-299, Simpson 1979: 79).

Àwọn èdè ilẹ̀ àjèjì mìíràn ṣì ń wúlò síwájú sí i gegebí ilò ṣe ń yọjú fún wọn. Pẹ̀lúpẹ̀lú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ àti ohun iyebíye ti àṣà Nàìjíríà, fún àpẹẹrẹ, nínú iṣẹ́ ọnà àti àṣà, bọ́ sí ojútáyé gbogbo àgbáyé nípa lílo èdè Gẹ̀ẹ́sì, àti nípasẹ̀ ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè lẹ́yìn àkókò ìgbòmìnira. Àwọn abala tó wà lẹ́yìn èyí ṣe àfihàn àwọn kan lára àwọn ẹ̀ka náà tí ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè ti gbòde ní Nàìjíríà lóde òní.

Ìsòwò ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè

Nàìjíríà ń kó ipa aṣiwájú tí ó ṣe pàtàkì nínú tàbí pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àjọ àgbáyé bí i Àjọ ilè Áfíríkà (AU), Àjọ ilẹ̀ Yúróòpù (EU), Àjọ Ọrọ̀ Ajé ní àwọn Orílé-Èdè Áfíríkà ti Ìwọ̀ Oòrùn (ECOWAS), àti Ilé ìfowópamọ́sí ti Ìdàgbàsókè Áfíríkà, níbití Nàìjíríà ti ní ìpín tí ó pọ̀jù pẹ̀lú agbára ìdìbò tí ó ga jùlọ.Nítorí ìdí èyí, ó jẹ́ dandan pé kí ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tí ó wà láàárín Nàìjíríà àti àwọn orílẹ́-èdè míràn tí ó wà nínú ìbáṣepọ̀ orílẹ́-èdè sí orílẹ̀-èdè kí ó dán mọ̣́rán. Nítorí náà, àwọn òṣìṣẹ́ ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè jẹ́ olùkópa pàtàkì nínú iṣẹ́ tí ó ń lọ ní Nàìjíríà òde òní. Àwọn èdè tí a fi ń ṣiṣẹ́ tí ó wọ́pọ̀ ní àjọ ECOWAS, àjọ AU àti ti Ilé ìfowópamọ́sí ti Ìdàgbàsókè Áfíríkà ni èdè Lárúbáwá, Gẹ̀ẹ́sì, Faransé, Pọtugíìsì àti èdè àwọn ará Sípéènì. Iṣẹ́ ̀itumọ̀ àwọn ojú òpó ẹ̀rọ ayélujára sí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn èdè iṣẹ́-ìjọba àti / tàbí sí àwọn èdè àbínibí, ìpèsè sílẹ̀ àti ìtẹ̀jáde àwọn àkọsílẹ̀, àti pàápàá iṣẹ́ ògbufọ̀ èdè ní àwọn ìpàdé kan àwọn atúmọ̀ èdè àti ògbufò èdè.

Ju bẹ́ẹ̀ lọ, Ilé-iṣé ìṣòwò fíìmù àgbéléwò ti Nàìjíríà, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Nollywood, nílò àkíyèsi. Nàìjíríà ni a mọ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ sí orílé-èdè kejì tí ó tóbi jù lọ ní àgbáyé tí ó ń ṣe àgbéjáde fíìmù àgbéléwò. Nítorípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù Nollywood ni ó ń jẹ́ wíwò ní àgbáyé, ọ̀pọ̀ àwọn tí ó ń ṣe fíìmù jáde ma ń lo àwọn iṣẹ́ èdè, láti ṣe ̀itumọ̀ èdè àkọsílè àwọn ̣ọ̀rọ̀ tí à ń sọ nínú fíìmù náà sí Gẹ̀ẹ́sì àti / tàbí èdè miràn (Ibbi: 48). Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé a ri pé dídára àwọn ìtumọ̀ èdè àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ inú fíìmù kéré ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn fíìmù tí à ń polówó ní gbàgede àgbáyé bí i Netflix àti àwọn gbàgede míràn ti ìbílẹ̀, ń gbìyànjú láti ní àmúyẹ ti ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ fún àwọn àpèjọ ènìyàn ní àgbáyé (Agbese 2019: 1267).

Iṣẹ́ ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè tún jẹ́ lílò nínú iṣẹ́ ìròyìn Nàìjíríà, lákòkọ́ọ́, nítorí i títóbi àkójọpọ̀ àwọn èdè ti orílẹ̀-èdè náà, àti èkejì, níwọ̀n ìgbàtí Nàìjíríà pàápàá ń bá àgbáyé tí ó tóbi jù ú lọ sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ gbígbé ìròyìn sí inú afẹ́fẹ́, ìtàn ìròyìn inú fíìmù ti ìjọba àti ti àwọn ẹgbẹ́ àǹfàní tí kì í ṣe ti ìjọba. Ìtumọ̀ èdè pẹ̀lú ohùn lórí ìròyìn kíkà àti ìtumọ̀ àkọsílẹ̀ ìròyìn ní èdè míràn ni à ń lò lemọ́lemọ́ nínú àwọn ohun èlò ìgbéròyìnjáde. Àwọn èdè iṣẹ́ ní ẹ̀ka iṣẹ́ yìí ma ń jẹ́ èyíkéyìí nínú àwọn èdè orílẹ̀-èdè, pàápàá jù lọ àwọn èdè agbègbè tí ó ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ mílíọ̀nù ènìyàn tí ó ń sọ wọ́n, àti Gẹ̀ẹ́sì (wo Ilé-Iṣẹ́ ìròyìn ti Ilẹ̀ Oba Gẹ̀ẹ́sì, BBC ní èdè Haúsá), tí ó ti ń ṣiṣẹ́ láti ọdún1957, ti BBC ní èdè Píjìn láti ọdún 2017, gẹ́gẹ́bí èdè Píjín ní Ìwọ̀ Oòrùn àti Àárín Áfíríkà, ti BBC ní èdè Íbò àti ní èdè Yorùbá láti ọdun 2018, àti Ndukwe 2013: 3-9 lórí i ìgbóhùnjáde ní èdè agbègbè àti ní èdè ilẹ̀ àjèjì ní Ilé Akéde Nàìjíríà (Voice of Nigeria - VON).

Ìtumọ̀ èdè ìwé tí a ti kọ sì tún ń tẹ̀síwájú láti máa jẹ́ pàtàkì níwọ̀nbí ọ̀gọ̀ò́rọ̀ ìwé tí a ti ṣe ìtumọ̀ wọn ti wá di kókó àgbéyèwò ìtumọ̀ èdè nínú àwọn ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè (TIS) ní Nàìjíríà (Adeyefa 2017). Díẹ̀ nínú àwọn àròsọ inú ìwé ní ìsaájú àti àwón tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ tí ó dá lórí àwùjọ-òṣèlú ilẹ̀ Nàìjíríà, tí a kọ́kọ́ kọ ní àwọn èdè Nàìjíríà àti ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, ni a ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìtumọ̀ wọn sí èdè Yúróòpù ní àípẹ̀ yí. Fún àpẹẹrẹ, En quête de changement (Afolabi 2023), jẹ́ ìtumọ̀ àkọsílẹ̀ eré ìtàgé Omonigho tí à ń pè ní A quest for change (2018). Ògbójú ọ̣dẹ nínú igbó Irúnmọlẹ̀, tí a ti dárúkọ rẹ̀ saájú, ni a ti túmọ̀ rẹ̀ sí èdè Jémáǹi gẹ́gẹ́bí Díẹ̀ befremdlichen Abenteuer von Àkàrà-Ògùn (Olalere 2022). Àpẹẹrẹ míràn ni Half of the Yellow Sun (2006) ti Adichie, tí a túmọ̀ rẹ̀ sí èdè orílẹ̀-èdè Nọ́wè gẹ́gẹ́bí En halv gul sol (Lange 2007). Nínú àkànṣe iṣẹ́ ìtumọ̀ ìwé tí a ti kọ tí a pè ní Nigerian Literature in French Translàtion (Ìtumọ̀ Lítírésọ̀ Nàìjíríà ní èdè Faransé), Madueke (2023) pèsè àkójọpọ̀ détà ti àwọn ìwé ìtàn àròsọ Nàìjíríà tí a ti ṣe ìtumọ̀ wọn sí èdè Faransé ní Orílẹ̀-èdè Faransé láti ọdún 1953.

Ní àfikún, ìtumọ̀ àkọsílẹ̀ ẹ̀sìn sì tún ń jẹ́ pàtàkì lónìí pàápàá, nítorí a kò ì tí ì ṣe ìtumọ̀ àti Bíbélì àti Kùráánì tán sí gbogbo èdè Nàìjíríà. Àwọn àjọ ànfààní kan tí kì í ṣe ti ìjọba ń kọ́ àwọn atúmọ̀ èdè Bíbélì, ògbufọ̀ àti / tàbí oníròyìn ohùn tí a gbà sílẹ̀ (ti ìtumọ̀ èdè Bíbélì) fún ìlò ẹ̀sìn. Iŕu àwọn àjọ wọ̀nyí náà ni o ní ojúṣe ìtumọ̀ sí oríṣiríṣi èdè. Ìdàgbàsókè kan tí ó ṣẹḷ̀e láìpẹ́ ni àṣeparí ìtumọ̀ èdè Bíbélì sí èdè Nàìjíríà mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (27) ní ọdún 2022, láti ọwọ́ ọ Ẹgbẹ́ Bíbélì ti Nàìjíríà (BSN), ẹgbẹ́ àgbájọpọ̀ àwọn Krìstẹ́nì tí ń ṣe ìtumọ̀ Bíbélì sí àwọn èdè Nàìjíríà. Ọ̀kan nínú àwọn iṣẹ àkànṣe BSN ní ọjọ́ iwájú ni láti rí i dájú pé Bíbélì wà ní àrọ́wọ́tó ní èdè àwọn adití. Wycliffe Internàtional jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àjọ míràn tí ó ń ṣe agbátẹrù fún ìtumọ̀ èdè Bíbélì ní Nàìjíríà (wo Wycliffe, Ile ẹ̀kọ́ Bíbélì ti Àríwáa Nàìjíríà, àti Warren-Rothlin 2012: 41-44 pẹ̀lú).

Lónìí, ó ti di àṣà tí ó jẹ́ mímọ̀ pé kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ijosin àti ètò àwọn ẹgbẹ́ Kristeni àti Ìslàámù wáiyé pẹ̀lú ̀iṣẹ́ ògbufọ̀ èdè láti / àti sí èdè Gẹ̀ẹ́sì àti àwọn èdè Nàìjíríà. Iṣẹ́ ògbufọ̀ èdè wà ní àwọn èdè ilẹ̀ àjèjì, nígbàtí a bá bèère fún wọ́n. Díẹ̀ nínú àwọn èlò agbéròyìn jáde (fún àpẹẹrẹ, ìwàásù inú amóhùnmáwòrán, àti àwọn ìwé) tí àwọn ìjọ oríṣiríṣi gbé jáde, ni a ti ṣe ìtumọ̀ wọ́n sí àwọn oríṣiríṣi èdè àjèjì (Rhapsody of Realities, ìtumọ̀ èdè iwaasu / ìròyìn). Lápá kan, èyí ṣẹlẹ̀ nítorí ìtànkálẹ̀ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìjọ Nàìjíríà sí àwọn orílẹ̀ míràn, tí ó sì mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ní èdè ti agbègbè àṣà titun jẹ́ kòṣeémánìí.

Nípa ti Kùráánì, láti àtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ní ọdún 1906, a ti ṣe àwọn akitiyan kọ̀ọ̀kan láti mú kí ìtumọ̀ èdè rẹ̀, tí àwọn alárìíwísí kan gbàgbọ́ pé kò kún ojú ìwọ̀n, dára sí i, nítorí pé kì í ṣe Mùsùlùmí ni ó ṣe é, (wo abala ìtumọ̀ èdè ẹ̀sìn). Gẹ́gẹ́bí Oyewumi (2022) ti wí:

Due to the controversy of how the Quran was published and its aim, some Muslims give a second thought about it, that is what prompted the Sardauna of Sokoto (Sir Ahmadu Bello), then the prime minister of Northern Nigeria, to move the motion for the first time to Mecca, to an organisation called Muslim World League (THE MUSLIM WORLD ULAMA) in Saudi Arabia, where he was a member at the time. "At the meeting, he stated that the Quran, which those he represents are reading, was written by a reverend […]". The Muslim World League agreed to assist them if the Yoruba Muslims could write the translation of the Quran on their own.

Oyewunmi tún sọ nípa àwọn oǹiṣẹ́ ìpínfúnni ti Ahmadiyya ní gbogbo àgbáyé tí wọ́n ń pín àwọn ìwé àti àwọn ìwé pélébé lórí àwọn ìgbàgbọ́ àti ìlànàa wọn. Nínú gbogbo ìtàn akitiyan ẹ̀sìn wọ́n, ọ̀kan nínú àwọn àkànṣe ̀iṣẹ́ wọ́n ni ìtumọ̀ èdè Kùráánì sí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn èdè pàtàkì, àwọn èdè Nàìjíríà pẹ̀lú.

Àwọn ohun tí ọjà ń bèèrè

Gẹ́gẹ́bí a ti sọ síwájú, ìdí tí a fi nílò iṣẹ́ ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè ni wípé àwọn tí ó ń sọ oríṣiríṣi èdè ní Nàìjíríà nílò láti ní ìbáraeniṣepọ̀. Nítorí náà, ó hàn gbangba pé à ń bèèrè fún àwọn òsìṣẹ́ iṣẹ́ èdè. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ìwádìí díẹ̀ ni ó wà, nínú èyítí a ti ṣe ìwádìí àwọn àìtó wọ́nyí àti àkọsílẹ̀ wọ́n ní ìlànà pẹ̀lú ìrírí àti àwòfín.

Oyetoyan (2016: 223-237) se ìwádìí láàárín àwọn tí ó ń lo iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè, tí àwọn tí o ti gboyè jáde ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ èdè ilẹ̀ àjèjì ní Nàìjíríà ṣe, pẹ̀lú ìfojúsí èdè Jẹ́máǹi. Àwọn bi aárùńlélàádọ́ta nínú ógọ́rùń (55%) láàárín àwọn tí ó kópa nínú ìwádìí yìí jẹ́rìí sí lílo iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè ní àwọn ẹ̀ka ̀iṣẹ́ bí i àwọn ilé-̀iṣẹ́ ìṣúná owó, èdè àti àṣà, ìpolówó ọjà, àjọ ànfààní tí kì í ṣe ti ìjọba (NGO), epo àti gáàsì, ìpolówó ìṣòwò àti àwọn ilé-̀iṣẹ́ atúmọ̀ èdè (Oyetoyan 2016: 227). Gẹ́gẹ́bí wọ́n ti ṣe sọ, irú àwọn iṣẹ́ ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè tí ó jọ iṣẹ́ tí àwọn òṣìṣẹ́ iṣẹ́ èdè máa ń ṣe le jẹ́ àwọn iṣẹ́ akọ̀wé elédè méjì, iṣẹ́ gẹ́gẹ́bí olùgbàlejò, alábòójútó ètò, tàbí ẹmẹ̀wà sí ilé aṣojú orílẹ̀-èdè, olùrànlọ́wọ́ àwọn oníbàráà, ol̀ukọ̀wé onímọ̀ pàtàkì àti/tàbí alátùńṣe, àti ògbufọ̀ èdè. (Oyetoyan 2016: 230). Nínú ìwádìí míràn, àwọn os̀iṣẹ́ ̀iṣẹ́ èdè tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àpapọ̀ èdè mẹ́fà tí ó yàtọ̀ sí ara wọn (Yorùbá, Gẹ̀ẹ́sì, Jémáǹi, èdè Ítálì, Faransé àti èdè Rọsíà), sọ àwọn ìpele agbaniṣíṣẹ́ mọ́kànlá (11) tí ó yàtọ̀ sí ara wọn (Oyetoyan 2016: 240, 244). Ìwé ile ̀iṣẹ́ àti ìwé fún ìtumọ̀ ohùn inú ìròyìn jẹ́ ara irú àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí àwọn tí ó kópa nínú ìwádìí yìí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú. Àwọn àkọsílẹ̀ àkànṣe iṣẹ́ míràn ni àwọn tí ó jẹ mọ́ òfin, ìsúná owó, ìṣòwò, ẹ̀sìn, ìmọ̀ èrọ, ìṣègùn, àti elégbòogi (Oyetoyan 2016: 242).

Bákan náà, ìwádìí tí ó dá lórí àlàyé àìtó nínú ọjà ìtumọ̀ èdè ní Nàìjíríà, láti ọwọ́ Afolabi (2018), fi han pé ìbéèrè ń wà fún ̀iṣẹ́ ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè ní orile-èdè náà. Gẹ́gẹ́bí ìwádìí yi, àwọn ẹ̀ka ńlá níbití a sábà ti ń ma ń bèèrè fún iṣẹ́ ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè ní ẹ̀ka iṣẹ́ àwùjọ, ti aládáni, ti ẹ̀sìn, ti fíìmù (Nollywood) àti ti àwón ẹ̀ka àjọṣepọ̀ àgbáyé, tí àwọn èdè tí ó sì ṣe pàtàkì jẹ́ Gẹ̀ẹ́sì, Faransé, Pọtugíìsì, àti àwọn èdè orile-èdè Nàìjíríà mẹ́ta, tí í ṣe Haúsá, Íbò àti Yorùbá (Afolabi 2018: 122-123).

Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn èsì ń fihàn pé, níti bí iṣẹ́ ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè tí ó wà ní orile-èdè ti pọ̀ tó àti pàápàá, bí ó ti dára tó, wọ́n kò tó oju ìwọ̀n tí à ń bèèrè fún, èyítí ó fi ìdí ọ̀rọ̀ Amosu (2010:78) múlẹ̀ pé:

There is a considerable amount of unethical and thoroughly unprofessional practices which have made Nigeria a free space for all kinds of interlopers who have even been known to engage in character assassination, in the name of jostling for contracts. Invariably, conference organisers who seek the cheap way […] end up with all types of distressing performances […]

Àwọn ẹgbẹ́ ọ̀mọ̀wé àti akọ́ṣẹ́mọṣẹ́

Ẹgbẹ́ ọ̀mọ̀wé titun kan, tí a ń pè ní Ẹgbẹ́ Ẹkọ́ ti Ìtumọ̀ Èdè ti Nàìjíríà (Translation Studies Association of Nigeria -TSAN), ni a ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ ní yunifásítì kan ní ìhà gúúsù ìwò oòrùn ní Nàìjíríà ní oṣù kọkànlá ọdún 2019. TSAN jẹ́ ọmọ Ẹgbẹ́ fún Ẹgbẹ́ Ẹkọ́ Ìtumọ̀ Èdè ní Áfíríkà (ATSA) tí a dá sílẹ̀ ní odún 2016 ní Yunifásítì ti Náíróbì ní Orílè-Èdè Kẹ́ńyà.

Logos
Ààmì ìdánimọ̀ ti NITI àti ti TSAN

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wipé ọ̀pọ̀ ǹkan ni ó ṣì yẹ láti ṣe nípa ti sísọ iṣẹ́ ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè di ojúṣe akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nìkan ní Nàìjíríà, àwọn atúmọ̀ àti ògbufọ̀ èdè ní orílẹ̀-èdè náà ni a ń kó papọ̀ lábẹ́ àjọ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí a mọ̀ sí Nigeria Institute of Translators and Interpreters (NITI), ẹ̀ka ti Nigerian Association of Translation and Interpreters (NATI) ti ìgbà kan rí, tí a dá sílẹ̀ ní ọdún 1978. Àwọn ohun tí a lè dárúkọ lára àwọn ìran NITI ni ìfúnláṣẹ, ìfúni ní ìwé ẹ̀rí àti ìfisábẹ́òfin ti àwọn ̀iṣẹ́ ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè ní Nàìjíríà. Àbádòfin láti fún NITI ní ̀idánimọ̀ ti olófin ti ìjọba Nàìjíríà  ni a ti gbé síwájú Ilé Aṣòfin, níbití ó ti ní ìgbohùnsọ fún gbogbo àwùjọ ní ọdún 2021. Gẹ́gẹ́bí ìròyìn tí ó wà lórí òpó ayélujára ti NITI:

When the bill is passed and it becomes Law, it will make the practice  of translation and interpretation managed in such a way that all language  practitioners in the country would be adequately trained, inducted, certified  (sworn), regulated and protected, to the greater benefit of the professionals, discouraging any untrained and unprofessional elements who might try to  tarnish the professional image of translation and interpretation in Nigeria, exactly like it is in other professions: Accountancy, Law, Medicine, Engineering, etc.

Ìrin àjọ̀ NITI láti gba ìdánimọ̀ ìjọba gùn, ó sì nira nítorí ìdínkù iṣẹ́ ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè sí ètò ̀iṣẹ́ ojojúmọ́ láṣán ní àwọn ile-̀iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ àti ní àwọn tí ìjọba ṣagbátẹrù wọ́n. Àjọ náà ti rí ìdàgbàsókè mélòó kan láàárín ogójì ọdún (40 years). Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n àti àwọn ìmúyẹ tí ó yẹ kí ó pọn dandan fún iṣẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ni a kò ì tí́̀ì sọ di òfin.

Gẹ́gẹ́bí ọ̀pọ̀ iṣẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ní ayé ìgbàlódé, NITI ti Nàìjíríà náà ní àwọn àpapọ̀ ọ̀pá ìdíwọ̀n àti ìṣe tí a fi ń darí i rẹ̀. Nínú ìtàn, NATI, tí í ṣe ìyá fún àjọ náà, ni a gbà wọlé ní ọdún 1981 láti di ọmọ ẹgbẹ́ àjọ àgbáyé fún àwọn Atúmọ̀ Èdè (FIT). Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé a kò dárúkọ ohunkohun nípa àjọ (NITI) yìí gẹ́gẹ́bí ọmọ ẹgbẹ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí lórí ojú òpó ayélujára ti àjọ àgbáyé FIT , ìfiwéra ọ̀nà ìṣiṣé láti òpó ayélujára àwọn àjọ méjèèjì wọ̀nyí fihàn pé FIT kì í gbà kí àwọn akẹ́kọ̀ó di ọmọ ẹgbẹ́. Àmọ́ NITI a máa gba àwọn tí ó ń sọ èdè púpọ̀ tí wọ́n ní oyè ẹ̀kọ́ àti àwọn akẹ́kọ̀ó èdè wọle. Nítorí náà, àwọn tó ń sọ èdè méjì àti àwọn tó ń sọ èdè púpọ̀ pẹ̀lú ìjáfáfá nínú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti èdè tí a fẹ ṣe ìtumọ̀ sí, ṣùgbọ́n tí wọ́n kò ní àmúyẹ ẹ̀kọ́ tàbí ti akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, ṣì le gba iṣẹ́ ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè ṣe ní ọ̀nà tí a là sílẹ̀ lábé àṣẹ àti ni ọ̀nà tí kì í ṣe pẹ̀lú àṣẹ ní Nàìjíríà.

Àwọn onímọ̀ èdè àti/tàbí àwọn tí ó ń sọ èdè púpọ̀ tí ó bá ń fẹ́ di ọmọ ẹgbẹ́ àjọ NITI ní láti ṣe ìdánwò ìfúnláṣẹ tí ó ní ipa méjì, kíkọ àti sísọ. Làti di ọmọ ẹgbẹ́ nínú àjọ náà yàtọ̀ síra, gẹ́gẹ́bí àwọn èdè oríṣiríṣi tí a rí lójú òpó ayélujára náà. Àwọn èdè mẹ́tàlá (13) li a kọ sílẹ̀, nínú èyítí mẹ́ta jẹ́ èdè ìbílẹ̀, yàtọ̀ sí Gẹ̀ẹ́sì, tí gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ mọ̀. Àwọn èdè iṣẹ́ mẹ́tàlá (13) wọ̀nyí àti iye àwọn onímọ̀ èdè tí a kọ sílẹ̀ fún wọn nì wọ̀nyí: Haúsá (mẹ́ta, 3), Íbò (mẹ́jọ, 8) àti Yorùbá (mẹ́ta, 3), Lárúbáwá (méje, 7), èdè Ṣáínà (méjì, 2), Faransé (ogójì, ó dín mẹ́ta, 37), Jémáǹi (1), èdè Ítálì, Látìnì̀ (ọ̀kan, 1) àti èdè Sípéènì (mẹ́ta, 3). Kò sí àtẹ̀jáde iye àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú èdè Ítálì, Pọtugíìsì, tàbí èdè Rọṣíà nígbà tí à ń kọ àròkọ yiì. Iye àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tí a kọ sílẹ̀ fún àwọn èdè kọ̀ọ̀kan tí a ń fi ṣiṣẹ́ tọ́ka sí àwọn èdè tí ó ṣeéṣe kí a máa bèèrè fún púpọ̀.

Niti àwọn àṣà ti ẹ̀kọ́, ní àsìkò lẹ́yìn òmìnira Nàìjíríà, ṣíṣe iṣẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ní àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ méjì ti ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè farahàn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Làti ìgbà náà lọ ni àwọn akẹ́kọ̀ó èdè ilẹ̀ àjèjì (fún àpẹẹrẹ, àwọn èdè Faranse, Jémáǹi, Pọtugíìsì, àti Lárúbáwá) ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga ti Nàìjíríà (pàápàá jùlọ, àwọn yunifásítì), ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gba ẹ̀kọ́ ìtumọ̀ èdè gẹ́gẹ́bí apá kan lára ètò ẹ̀kọ́ wọ́n, nípa bẹ́è, a fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún àwọn kan nínú wọn tí yóò di akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ atúmọ̀ àti ògbufọ̀ èdè ní ọjọ́ iwájú (Simpson 2007, Amosu 2010). Ọ̀nà Ìtumọ̀ èdè nípasẹ̀ Gírámà (Grammar Translation Method), tí a tún ń pè ní 'fífi ìtumọ̀ èdè' kẹ́kọ̀ó, jẹ́ ọ̀nà sí ohun tí ó jà jù nínú ìkọ́ni ti èdè ilẹ̀ òkèèrè ní àsìkò ìmúnisìn, tí ó sì wá jásí pé òpin tí à ń lépa nínú àwọn ìdánrawò ìtumọ̀ èdè kì í ṣe ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ bí a ṣe le rí i ní ̀ìṣẹ̀lẹ̀ ìtumọ̀ èdè gidi (Delisle 1988: 26). Ní àwọn àsìkò lẹ́yìn ìmúnisìn, ìtumọ̀ èdè, kì í ṣẹ́ ògbufọ̀ èdè, ni ó dàbí kókó pàtàkì nínú ẹ̀kọ́ èdè ilẹ̀ àjèjì (Olaoyè & Otunuyi 2009: 122, Anyaehie 1994: 19-24). Ìtumọ̀ èdè ti wà lára ètò ẹ̀kọ́ tí ó ń yọrí sí oyè ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ (bachelor's degree) nínú àwọn Èdè Yúróòpù òde oní ní àwọn yunifásítì Nàìjíríà.

Ṣùgbọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìtumọ̀ èdè wà nínú ẹ̀kọ́ àwọn Èdè Yúróòpù òde òní ní Faransé, Jémáǹi, Pọtugíìsì, èdè Rọṣià àti ti Ítálì, wọ́n kò jẹ́ kíkọ́ nítorí wípé kí a le lò wọ́n fún iṣẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ (Kolawole 2022 :33). Síbẹ̀síbẹ̀, ní ìṣe, àwọn olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ó ní ẹ̀ka èdè ilẹ̀ àjèjì ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga ma ń gba iṣẹ́ ní ọ̀nà tí a là sílẹ̀ lábé àṣẹ tàbí ni ọ̀nà tí kì í ṣe pẹ̀lú àṣẹ. Ṣíṣe ìtumọ̀ tàbí ògbufọ̀ èdè ní ojúlówó ọ̀nà fún àwọn ìpàdé ní àwọn àjọ ìbílẹ̀ tàbí tí àgbáyé má a ń já sí pé kí a san owó tí a kò lè dúnàádúrà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìsanwó nígbàtí kì í bá ṣe ọ̀nà tí a là sílẹ̀ lábé àṣẹ le jẹ́ nípa ìdúnàádúrà (Ukoyèn 1979: 74, Oyetoyan 2016: 221-222). Ní ibi tí a dé yìí, ó le ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ̀akíyèsi pé ìwúrí àwọn kan nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó gboyè nínú ẹ̀kọ́ èdè ilẹ̀ àjèjì láti bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ìtumọ̀ èdè tàbí ẹ̀kọ́ tí a yà sọ́tọ̀ lẹ́yìn ìgbà náà, ni wọ́n rí nínú àwọn ìdánrawò ìtumọ̀ èdè nígbàtí wọ́n ń kọ́ ẹ̀kọ́ bí ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ gíga tí kò ì tíi gba oyè àkọ́kọ́. Nítorí náà, ó dàbí i wípé iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè ti ní àwọn ìdí láti tẹ̀síwájú nítorí wíwà àwọn èdè ilẹ̀ àjèjì àti nítorí pé ó ṣeéṣe láti pa owó.

Níti ògbufọ̀ èdè, ìbáṣepọ̀ láàárín àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àjọ Áfíríkà (AU) ti di ìdí tí ó hàn gbangba fún ṣíṣe ògbufọ̀ àwọn ìpàdé àti ṣíṣe ìtumọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì sí àwọn èdè ìjọba tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ń lò. Èyí pàápàá tún mú kí ìbéèrè wá sí àwọn ilé ẹ̀kọ́ ti Nàìjíríà láti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ó fún àwọn oníṣẹ́ èdè fún iṣẹ́ ògbufọ̀. Fún Timothy-Asobele (1999: 60-61), tí ó tọpinpin ìbẹ̀rẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ó akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ fún ìtumọ̀ èdè ní Nàìjíríà, lẹ́yìn àjọ̀dún àwọn ènìyàn dúdú ti ilẹ̀ Áfíríkà fún àwọn iṣẹ́ ọnà àti ọ̀làjú (Negro-African Festival of Arts and Culture (FESTAC)) tí ó wáiyé ní ìlú Èkó, ní 1977, àwọn yunifásítì Naijira, àti Yunifásítì ìlú Èkó náà, bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àfihàn ẹ̀kọ́ ìtumọ̀ èdè fún akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nínú ètò ẹ̀kọ́ wọn. Bí ó ṣe ṣe àpèjúwe ìdàgbàsókè náà nì yí:

During this cultural festival, the services of the small number of professionally trained African translators and interpreters were stretched to the limit, and Nigeria alone with its five existing Universities in Ibadan, Lagos, Zaria, Ile-Ife, and Nsukka could not train the bilingual linguists necessary to service the various sectors of the Cultural Festival. (Timothy-Asobele 1999: 60) 

Gẹ́gẹ́bí àbájáde yìí, àwọn yunifásítì Nàìjíríà kan ti ṣe àgbékalẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ fún ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè (T&I) nínú àwọn èdè ilẹ̀ àjèjì tí a ti mẹnu bà tẹ́lẹ̀ àti nínú Gẹ̀ẹ́sì gẹ́gẹ́bí èdè ìpilẹ̀sẹ̀ àti èdè tí a fẹ́ ṣe ìtumọ̀ sí ní ìpele oyè kejì tí ó tẹ̀lẹ́ àwọn tí ó ti gboyè àkọ́kọ́ jáde (tí í ṣe Master tàbí Postgraduate Diploma). Èyí túmọ̀ sí pé a ń retí́ wípé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní láti jẹ́ olùṣàmúlò tí ó dángájíá nínu lílo àwọn èdè àsopọ̀ méjèjì.

padà sí òkè

[heading title] Ẹkọ́ ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè (TIS)

Ó jọ pé àwọn ọ̀mọ̀wé Nàìjíríà ní àsìkò ìgbàlódé wà ní iṣọ̀kan nínú ìgbéyẹ̀wò wọn lóríi bí TIS ṣe rí ní orílè-èdè náà. Ẹ̀ka yìí ni a ti dá mọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀ka ẹ̀kọ́ tí ó yàtọ̀ sí ẹ̀kọ́ àwọn èdè ilẹ̀ àjèjì láàárín àwọn ọ̀mọ̀wé Nàìjíríà nínú orílè-èdè náà àti ní àwọn ilẹ̀ àjèjì. Eyi dá lórí iye àwọn yunifásítì tí wọ́n ní ẹ̀kọ́ oyè kejì nínú ìtumọ̀ èdè. Yàtò sí èyí, gẹ́gẹ́bí a ti ṣe sọ síwájú, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé Nàìjíríà ni wọ́n ti kọ ìwé ìwádìí ti oyè dọkita ní ẹ̀ka náà, ní àwọn yunifásítì Nàìjíríà àti àwọn ti ilẹ̀ àjèjì. Síbẹ̀síbẹ̀, TIS ní Nàìjíríà ṣì wà ní àwọn ip̀ele àkọ́kọ́, àwọn ìsòro ìdàgbàsókè tó jẹ́ kókó sì jẹ̀ àìní àwọn olùkọ́ tí ó ní àmúyẹ àti àìní àwọn ohun èlò ẹ̀rọ tí ó bá ìdíwọ̀n mu (Kolawole 2022: 33, Afolabi/Oyetoyan 2021: 340-343). Àwọn abala tí ó tẹ̀lé èyí jẹ́ ìjíròrò lórí i ẹ̀kọ́ atúmọ̀ àti ògbufọ̀ èdè ní àwọn yunifásítì Nàìjíríà àti ipò ìwádìí nínú TIS láàárín àwọn ọ̀mọ̀wé Nàìjíríà.

TIS ní àwọn Yunifásítì Nàìjíríà

TIS ní Nàìjíríà, gẹ́gẹ́bí a ti ṣe mẹ́nu bàá tẹ́lẹ̀, ti n yípòpadà, kúrò ní ọwọ́ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ tí ó ní ẹ̀bùn sísọ èdè méjì tàbí púpọ̀ àti àwọn ará ilẹ̀ àjèjì tí ó ní ìfẹ́ ̀sí ìbáraeniṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ìbílẹ̀, sí ọwọ́ àwọn olùkọ́ tí ó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ mọ̀ọ́kọmọ̀ókà ní àwọn kíláàsì èdè, àti lẹ́yìn náà, ní àwọn kíláàsì èdè ilẹ̀ àjèjì. A ti tọ́ka tẹ́lẹ̀ rí sí ipò gbogbogbòò ti àwọn ètò ẹ̀kọ́ tí wọ́n ní ẹ̀kọ́ tí ó ń lo ìtumọ̀ èdè gẹ́gẹ́bí ohun èlò kíkọ́ èdè nínú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ètò ẹ̀kọ́ ti oyè yunifásítì àkọ́kọ́. Àmọ́, ila ìdàgbàsókè láìpé yìí ti fihàn pé ó ti jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà pé ìdàgbàsókè ṣe pàtàkì fún TIS gẹ́gẹ́bí èka iṣé akọ́ṣẹ́mọṣẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ pé ìgbésẹ̀ tí ó so pọ̀ pẹ̀lú èyí kò yá rárá, àwọn òṣìṣẹ́ àwọn yunifásítì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lù àwọn èdè tí a ń béèrè fún púpọ̀ nínú iṣẹ́ ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè, ti ṣe ìdáhùn sí ìbéèrè àwọn ìgbà wọ̀nyí, tí wọ́n sì ṣe àgbékalẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ fún TIS.

Bandia (2001: 301) jábò, fún àpẹẹrẹ, pé àwọn yunifásítì méjì fi àwọn ètò oyè ẹ̀kọ́ lẹ́yìn oyè àkọ́kọ́ lọ́lẹ̀, tí ìtumọ̀ èdè sì jẹ́ kókó. Pẹ̀lú èrògbà làti ṣe àyẹwò ìlosíwájú tí ó ti wà títí di ìsisìnyí ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ atúmọ̀ àti ògbufọ̀ èdè ní Nàìjíríà, Afolabi (2018: 149-200) ṣe ìwádìí láàárín àwọn yunifásítì Nàìjíríà mọ́kànlá (11) tí wọ́n ti ní, tàbí, ní́gbà náà, tí wọ́n ń ṣe ètò ẹ̀kọ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ní ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè , ní pàtó, ní ìpele tí ó ju oyè ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ ti yunifásítì lọ. Àwọn ètò oyè ẹ̀kọ́ míràn ní Orílẹ̀-èdè Kamerun, Kanada, Ghana àti Faranse ni a fi pẹ̀lú ìfìwéra tí a ṣe nínú ìwádìí náà. Àwọn àwárí fi ètò ẹ̀kọ́ tí a kò yà sọ́tọ́ hàn, (ìyẹn ni pé, oyè M.A. ní ètò ẹ̀kọ́ Faransé pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ìtumọ̀ èdè, dípò ètò ẹ̀kọ́ M.A. ní Ìtumọ̀ Èdè), àìní ìdánwò ìgbàwọlé tí ó pọn dandan àti pàápàá àìní ètò ẹ̀kọ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ti ìpele oyè ẹ̀kọ́ yunifásítì kejì, pẹ̀lú àsìkò ẹ̀kọ́ tí yóò jẹ́ ọdún méjì. Ìwádìí náà tún ròyìn pé kò sí yunifásítì Nàìjíríà kankan lọ́wọ́lọ́wọ́ tí ó ní ìtumọ̀ èdè gẹ́gẹ́bí ètò ẹ̀kọ́ tí ó dá dúró ní ìpele oyè yunifásítì àkọ́kọ́. Ní àfikún, àwọn èsì tọ́ka si pé ó ṣe kókó làti fi àwọn èdè mejeeji ti a le túmò sí sínu ẹ̀kọ́ ìtumọ̀ èdè fún èdèkèdè tí ó jẹ́ àjèjì tàbí ti ilẹ̀ Nàìjíríà tí a bá yàn, àti pé kí a sì fi ìrírí ògidi pẹ̀lú rẹ̀ nípasẹ̀ ìkọ́ṣẹ́ tí ó pọn dandan láàárín àsìkò ẹ̀kọ́ (Afolabi 2018: 203-224).

Oyetoyan (2016: 256-260), tí ìwádìí re da lórí ẹ̀kọ́ èdè àti àṣà Jémáǹi ní Nàìjíríà, ṣe àtúnyèwò ètò ẹ̀kọ́ oyè kejì nínú ìtumọ̀ èdè (Jémáǹi si Gẹ̀ẹ́sì) tí wọ́n n se ní yunifásítì Nàìjíríà àkọ́kọ́, tí í ṣe Yunifásítì Ìbàdàn. Àtúnyẹ̀wò ètò ẹ̀kọ́ oyè kejì (M. A.) ní Ìtumọ̀ Èdè yí ni ó kó papọ̀ pẹ̀lú ìjíròrò inu ímeèlì pẹ̀lú enìkan tí a fi ọ̀rọ̀ lọ̀ tí ó jẹ́ oṣìṣẹ́ yunifásítì náà ní Ẹ̀ka àwọn Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù òde òní. Àwọn èsì àbájáde fi hàn pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìlànà ẹ̀kọ́ ti wà nílẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ǹkan ni ó wà nílẹ̀ tí ó nílò ìjíròrò. Fún àpẹẹrẹ, àwọn abala tí ó ṣe pàtàkì nínú iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè ní Nàìjíríà kò sí nínú àwọn ètò ẹ̀kọ́ yìí. Pẹ̀lúpẹ̀lú, kò ì tí ì sí ìjíròrò lórí ìṣòro ìtakété tí ó wà láàárín àṣà èdè ìtumọ̀, àti àìní àwọn ẹ̀rọ amáyédẹrùn fún iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè.

Nínú àyẹ̀wo ìsaájú tí Afolabi & Oyetoyan (2021) ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe, àwọn èsì náà tún fihàn pé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn yunifásítì Nàìjíríà ni wọ́n tí ń kíyèsi àwọn idiwọ́n tí ó wà nínú ẹ̀kọ́ àwọn atúmọ̀ àti ògbufọ̀ èdè. Síbẹ̀síbẹ̀, ní àsìkò ̀àj̀àkálè àrùn COVID-19, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ile ẹ̀kọ́ tí ó ń fún ni ní ìdánilẹ̣́kọ́ atúmọ̀ àti ògbufọ̀ èdè ni kò ní ànfààní láti ṣiṣẹ́ nítorí àìní àwọn ẹ̀rọ amáyédẹrùn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n àti àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí wọ́n ti gba ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú ìlò àwọn ẹ̀rọ náà. Èyí mú kí ó fẹ́rẹ̀ má ṣeéṣe láti yípadà sí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ayélujára (ti ojúkojú, ní ìṣẹ́jú àáyá àti ti èyítí a gba ohùn àti/tàbí àwòrán rẹ̀ sílẹ̀ fún líló nígbà tí ó bá yá) ní àsìkò àjàkálè àrùn, tí ó sì yàtọ̀ sí bí ǹkan ṣe rí ní àwọn ibòmíràn ní àgbáyé, níbití́ a ti mú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bá àìní ̀àwùjọ dọ́gba ní kíákíá. Àwọn tí ó kọ̀wé náà wá ojútùú sí ọ̀ràn náà nípa ríronú sí àwọn ìṣòro pàtó tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ Nàìjíríà.

Ìwádìí àti àwọn itejáde

A ti ṣàlàyé TIS gẹ́gẹ́bí ẹ̀ka-ìmọ̀ èyí tí ó so oríṣiríṣi ẹ̀ka pọ̀ (Wotjak 1999: 543-560). Láàárín ẹ̀ka ìmọ̀ yìí, oríṣiríṣi ẹ̀ka àti ona ló wà, èyí tí wọ́n ń ṣàpèjúwe ìgbésẹ̀ náà àti ohun tí o jáde láti inu ̀iṣẹ́ ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè (wo pípín sí ìsọ̀rí ti Holmes, tí a tọ́ka sí nínú Toury 2012: 8-9, Wang 2018: 154). Nínú TIS ní Nàìjíríà, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àfojúsùn náà ti wà lórí ohun náà tí o jáde, èyítí woń sábà máa ń pín sí ìtumọ̀ èdè àwọn ìwé tí a ti kọ, àwọn ìwé ìsìn àti ti àkọsílẹ̀ tí ó ní́ àṣẹ, bákan náà ni àgbéyẹ̀wò ìtumọ̀ èdè. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1980, àwọn ọ̀mọ̀wé nínú ẹ̀kọ́ èdè Faransé àti èdè Gẹ̀ẹ́sì bíi Abioyè, Ajiboyè, Amosu, Timothy-Asobele, Ojo, Simpson, Soyinka, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn mìíràn fojú sí, ó kéré, ó pọ̀, ìtúmọ̀ èdè ti ìwé tí a ti kọ. Àwọn kan lára wọn tilẹ̀ túmọ̀ àwọn àtẹ̀jáde ìwé tí a ti kọ láti àwọn èdè Yúróòpù sí àwọn èdè Nàìjíríà, àti ìdà kejì rẹ̀.

Ìyípadà kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ tí ó ń wáyé láti lílo ìtumọ̀ èdè́ bí ohun èlò nínú ẹ̀kọ́ èdè ilẹ̀ àjèjì sí lílo ẹ̀kọ́ ìtumọ èdè ̀fún ìmúlò iṣẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ni ó dá lórí àwọn ohun tí a ń bèèrè fún ní ọjà ní orílẹ̀-èdè elèdè púpọ̀ yìí. Nípa bẹ́ẹ̀, ìran àwọn ọ̀mọ̀wé nínú ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè tí wọ́n kéré ní ọjọ́ orí bíi Adeyefa, Afolabi, Birma, Madueke, Olalere, Oyali, Oyetoyan, Thomas, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ìfẹ́ ọkàn wọn hàn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ìwádìí tó ṣe pàtàkì (ìwé àkọparí oyè ẹ̀kọ́ kẹta - PhD àti àwọn àpilẹ̀kọ àtìgbàdégbà) lórí abala onírúurú tó jẹ mọ́ ẹ̀ka ẹ̀kọ́ náà. Àwọn kókó tí a gbájú mọ́ ni ẹ́kọ̀́ àwọn atúmọ̀ èdè, àkóso, ìmọ̀-ẹ̀rọ, àti àyẹ̀wòo didara. Ìwádìí nínú ìtumọ̀ èdè ìwé esìn àti ti ìwé tí a ti kọ tún jẹ́ kókó pàtàkì kan, bí ìtumọ̀ èdè Bíbélì fúnra rẹ̀ ti jẹ iṣẹ́ ńlá tí kò dáwọ́ dúró ní Nàìjíríà láti àwọn ọdún 1800, ó ṣì jẹ́ àṣà láti rí àwọn ọ̀mọ̀wé tí wọ́n ń ṣe àgbéyẹwo àwọn ìtumọ edè Bíbélì àti Kùránì nínú àwọn àtẹ̀jáde ìwádìí (wo Oyali 2018; Fakayode 2020, Adeyefa 2017).

JTSN
Ojú ewé àkọko ti atẹ̀jáde àkọ́kọ́ ti JTSN

Ìdàgbàsókè kan tí ó yẹ fún àfiyèsí nínú ìwádìí T&I ní Nàìjíríà ní ìfilọ́lẹ̀ láìpẹ́ yìí (ní 2022) ti ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti Journal for Translation Studies in Nigeria (JTSN), ìtẹ̀jáde ti Ẹgbẹ́ Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìtumọ̀ Ní Nàìjíríà (TSAN), ìdàgbàsókè tí ọ̀pọ̀ àwọn olùkópa nínú ètò gbà pé ó ti pẹ́ tí ó yẹ kó wáiyé.

A ti ṣe àfihàn ìtàn àti ipò TIS ní Nàìjíríà, èyí tó fi díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tí wọ́n ń dojú kọ lẹ́nu ẹ̀ka iṣẹ́ náà hàn. Ní ìkòríta yìí, kò sí iyèméjì kankan pé, ìbéèrè fún àwọn iṣẹ́ ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè yóò máa pọ̀ sí i bí Nàìjíríà ṣe ń tẹ̀síwájú láti fa àfiyèsí àgbáyé, nítorí pé Nàìjíríà ní orílẹ̀-èdè tí ó tóbi jù lọ ní Áfíríkà. Bí àpẹẹrẹ, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní orí ilé-iṣẹ́ àjọ ECOWAS wà, èyí sì mú kí ìlú Abuja àti ìlú Èkó - tí í ṣe olú ìlú ìsèlú àti olú ìlú ìṣòwò orílẹ̀-èdè náà - jẹ́ ibùdó ìbáṣepọ̀ ti ìṣèlú àti ti ìṣòwò láàríń àwọn orílẹ́ èdè yípo ọdún. Nítorí náà, ó túmọ̀ sí pé a ó nílò àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ atúmọ̀ àti àwọn ògbufọ̀ èdè láti lè bójú tó àwọn ìbéèrè ọjà tí o ń pọ̀ si. Èyí pàápàá tún ń fi ̀ipè síta fún ìgbékalẹ̀ àwọn ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ atúmọ̀ àti ògbufò èdè púpọ̀ sí i ní orílẹ̀-èdè náà. Nígbàtí́ yó fi di ọdún 2022, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn atúmọ̀ àti ogbufò èdè ní Nàìjíríà ni wọ́n ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní òkè okun tàbí tí wọ́n ti kọ ara wọn nípa ìrírí ní agbègbè ìbílẹ̀.

padà sí òkè

Research potential Ìwádìí Ojo Iwaju

Ìwádìí nínú ̀iṣẹ́ ìtumọ̀ àti ògbufọ̀ èdè (T&I) ni Nàìjíríà kò ì tí́ì dàgbà sókè. Lọwọ́lọ́wọ́ báyìí, àtẹ̀jáde nínú ẹ̀ka ẹ̀kọ́ yìí kò pọ̀ tó ní Nàìjíríà. Ìmọ̀ àti ìṣe iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè ní Nàìjíríà nílò láti ní àkọsílẹ̀ dáradára nípa ̀ikíyèsi tàbí ìrírí. Ỳaṭ̀o sí èyí, kò ì tí ì sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwádìí lórí lílo àwọn ohun èlò ìtumọ̀ èdè lórí ẹ̀rọ̀ ayárabíàṣá nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àwọn atúmọ̀ àti ògbufọ̀ èdè. Nítorí náà, eléyìì jẹ́ àlàfo pàtàkì tí ó wà nínú ìwádìí. Lákòtá́n, pẹ̀lú ipò gíga tí ilé iṣẹ́ fíìmù àgbéléwò – Nollywood - ti Nàìjíríà ní àgbáyé, a ní láti ṣe àyèwò nípa àkíyèsi ilé iṣẹ́ ìtumọ̀ amóhùn-máwòrán (AVT), pẹ̀lú lílò ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàárín àwọn yunifásítì àti àwọn ilé-iṣẹ́ tí ó wà ní agbègbè wọ́n, kí a s̀ fi kókó ẹ̀kọ́ yìí sí inu àwọn ètò ẹ̀kọ́ fún àwọn atúmọ̀ àti ògbufọ̀ èdè ní Nàìjíríà.

Gẹ́gẹ́bí ìyànjú Afolabi & Oyetoyan (2021), ó jẹ́ ọ̀ranyàn láti ṣe ìwádìí nípa àkíyèsi àti ìrírí, láti wá ojútùú si àwọn ohun tí o ní í ṣe pẹ̀lú ̀iṣẹ́ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ atúmọ̀ àti ògbufọ̀ èdè, àti pàápàá pẹ̀lú kíkọ́nilẹ́kọ̀ó wọn. A ní ìrètí wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àtẹ̀jáde àtìgbàdégbà ti akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ atúmọ̀ and ògbufọ̀ èdè ni yóò máa jáde ní gbogbo yunifásítì Nàìjíríà bi àwọn olùkọ́ bá ti ń kọ́ ẹ̀kọ́.

Ìdojúkọ tí ó wà pẹ̀lú dídára iṣẹ́ àwọn atúmọ̀ àti ògbufọ̀ èdè, dá lé orí ẹ̀kọ́ kíkọ́ wọn àti àtúnseẹ̀kọ́. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé ki àwọn ile-ẹ̀kọ́ gíga rí i dájú pé wọ́n mu àwọn kókó ẹ̀kọ́ wọ́n àti àwọn ohun tí ó ní láti ṣe pẹ̀lú wọ́n dé ojú ìwọ̀n, ki wọ́n sì mú kí ó dọ́gba pẹ̀lú ohun tí à ń bèèrè fún lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ọjà àgbáyé. Ọ̀nà kan tí a le fi ṣe èyí ni láti mú kí ó jẹ́ dandan fún àwọn akẹ̀kọ́ láti wà ní ilé-̀iṣẹ́ fún ìkíyèsi àti ìrírí ̀iṣẹ́, ki wọ́n tó gba oyè ẹ̀kọ́.

Àwọn ẹgbẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àti onìwádìí (NITI àti TSAN) náà ní ipa pàtàkì láti kó nínú ìfidímúlẹ̀ àti ìbójútó ìmúyẹ dídárá nípa rírí i dájú pé àwọn ènìyàn ń tẹ̀lé àwọn ìdíwọ̀n akọ́ṣẹ́mọṣẹ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ akitiyan tí ó dá lórí àròjinlẹ̀ ni ó ní láti jẹ́ ṣiṣe, kí ilé aṣòfin orílè-èdè kí ó le jíròrò lórí ìwé àbádòfin ti NITI, kí wọ́n sì fi ọwọ́ sí i, kí iṣẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ náà le ṣe é gbàgbọ́, kí a sì dáà mọ nípa ìlànà ti olófin.

Àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ atúmọ̀ àti ògbufọ̀ èdè tí ó dàbí ìbejì ni a ti dá mọ̀ sí ojúse àwọn akọṣémọṣẹ́ èdè, tí èyí sì jẹ́ ì̀dàgbàsókè tí ó bẹ́rẹ́ ní orílè-èdè Nàìjíríà saájú àsìkò ìmúnisìn. Ohun tí à ń fojú sọ́nà fún ni wípé àwọn ìrètí ìdàgbàsókè ní ẹ̀ka iṣẹ́ wọ̀nyí ní Nàìjíríà lónìí yóò di ohun tí ó wá sí ìmúṣẹ láìpẹ́.

padà sí òkè

Creado con eXeLearning (Ventana nueva)